Jer 32:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọdun kẹwa Sedekiah, ọba Juda, eyiti o jẹ ọdun kejidilogun ti Nebukadnessari.

2. Nigbana ni ogun ọba Babeli ha Jerusalemu mọ: a si se Jeremiah woli mọ agbala ile túbu, ti o wà ni ile ọba Juda.

Jer 32