Jer 31:33-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi.

34. Nwọn kì yio si kọni mọ ẹnikini ẹnikeji rẹ̀, ati ẹ̀gbọn, aburo rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo nwọn ni yio mọ̀ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn, li Oluwa wi; nitori emi o dari aiṣedede wọn ji, emi kì o si ranti ẹ̀ṣẹ wọn mọ.

35. Bayi li Oluwa wi ti o fi õrùn fun imọlẹ li ọsan, ilana oṣupa ati irawọ fun imọlẹ li oru, ti o rú okun soke tobẹ̃, ti riru omi rẹ̀ nho; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀:

36. Bi ilana wọnyi ba yẹ̀ kuro niwaju mi, li Oluwa wi, njẹ iru-ọmọ Israeli pẹlu yio dẹkun lati ma jẹ orilẹ-ède niwaju mi lailai.

37. Bayi li Oluwa wi, Bi a ba le wọ̀n ọrun loke, ti a si le wá ipilẹ aiye ri nisalẹ, emi pẹlu yio ta iru-ọmọ Israeli nù nitori gbogbo eyiti nwọn ti ṣe, li Oluwa wi.

Jer 31