Jer 31:19-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Lõtọ lẹhin ti emi yipada, mo ronupiwada; ati lẹhin ti a kọ́ mi, mo lu ẹ̀gbẹ mi: oju tì mi, lõtọ, ani mo dãmu, nitoripe emi ru ẹ̀gan igba ewe mi.

20. Ọmọ ọ̀wọn ha ni Efraimu fun mi bi? ọmọ inu-didùn ha ni? nitori bi emi ti sọ̀rọ si i to, sibẹ emi ranti rẹ̀, nitorina ni ọkàn mi ṣe lù fun u; emi o ṣe iyọ́nu fun u nitõtọ, li Oluwa wi.

21. Gbe àmi-ọ̀na soke, ṣe ọwọ̀n àmi: gbe ọkàn rẹ si opopo ọ̀na, ani ọ̀na ti iwọ ti lọ: tun yipada, iwọ wundia Israeli, tun yipada si ilu rẹ wọnyi.

22. Iwọ o ti ṣina kiri pẹ to, iwọ apẹhinda ọmọbinrin? nitori Oluwa dá ohun titun ni ilẹ na pe, Obinrin kan yio yi ọkunrin kan ka.

23. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Nwọn o si tun lò ède yi ni ilẹ Juda ati ni ilu rẹ̀ wọnni, nigbati emi o mu igbekun wọn pada, pe, Ki Oluwa ki o bukun ọ, Ibugbe ododo, Oke ìwa-mimọ́!

24. Juda ati gbogbo ilu rẹ̀ yio ma jumọ gbe inu rẹ̀, agbẹ, ati awọn ti mba agbo-ẹran lọ kakiri,

25. Nitori emi tù ọkàn alãrẹ ninu, emi si ti tẹ gbogbo ọkàn ikãnu lọrun.

26. Lori eyi ni mo ji, mo si wò; õrun mi si dùn mọ mi.

Jer 31