Jer 28:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kanna li atetekọbẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, li ọdun kẹrin ati oṣù karun, ti Hananiah, ọmọ Asuri woli, ti iṣe ti Gibeoni, wi fun mi ni ile Oluwa, niwaju awọn alufa ati gbogbo enia pe,

2. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Emi ti ṣẹ àjaga ọba Babeli.

3. Ninu akoko ọdun meji li emi o tun mu gbogbo ohun-èlo ile Oluwa pada wá si ibi yi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kó kuro ni ibi yi, ti o si mu wọn lọ si Babeli.

Jer 28