Jer 23:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Emi kò ran awọn woli wọnyi, ṣugbọn nwọn sare: emi kò ba wọn sọ̀rọ, ṣugbọn nwọn sọ asọtẹlẹ.

22. Ibaṣepe nwọn duro ni imọran mi, nwọn iba jẹ ki enia mi ki o gbọ́ ọ̀rọ mi, nigbana ni nwọn iba yipada kuro ni ọ̀na buburu wọn, ati kuro ninu buburu iṣe wọn.

23. Emi ha iṣe Ọlọrun itosi? li Oluwa wi, kì iṣe Ọlọrun lati okere pẹlu?

24. Ẹnikẹni le fi ara rẹ̀ pamọ ni ibi ìkọkọ, ti emi kì yio ri i, li Oluwa wi. Emi kò ha kún ọrun on aiye, li Oluwa wi?

25. Emi ti gbọ́ eyiti awọn woli sọ, ti nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ mi wi pe, Mo lá alá! mo lá alá!

26. Yio ti pẹ to, ti eyi yio wà li ọkàn awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ eke? ani, awọn alasọtẹlẹ ẹ̀tan ọkàn wọn.

27. Ti nwọn rò lati mu ki enia mi ki o gbàgbe orukọ mi nipa alá wọn ti nwọn nrọ́, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀, gẹgẹ bi awọn baba wọn ti gbagbe orukọ mi nitori Baali.

28. Woli na ti o lála, jẹ ki o rọ́ ọ; ati ẹniti o ni ọ̀rọ mi, jẹ ki o fi ododo sọ ọ̀rọ mi. Kini iyangbo ni iṣe ninu ọkà, li Oluwa wi?

29. Ọ̀rọ mi kò ha dabi iná? li Oluwa wi; ati bi òlu irin ti nfọ́ apata tútu?

Jer 23