Jer 23:13-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Emi si ti ri were ninu awọn woli Samaria, nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ Baali, nwọn si mu Israeli enia mi ṣina.

14. Emi ti ri irira lara awọn woli Jerusalemu, nwọn ṣe panṣaga, nwọn si rìn ninu eke, nwọn mu ọwọ oluṣe-buburu le tobẹ̃, ti kò si ẹnikan ti o yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀; gbogbo wọn dabi Sodomu niwaju mi, ati awọn olugbe rẹ̀ bi Gomorra.

15. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti awọn woli; Sa wò o, emi o fi wahala bọ́ wọn, emi o si jẹ ki nwọn ki o mu omi orõro: nitori lati ọdọ awọn woli Jerusalemu ni ibajẹ ti jade lọ si gbogbo ilẹ na.

16. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ máṣe feti si ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin: nwọn sọ nyin di asan, nwọn sọ̀rọ iran inu ara wọn, kì iṣe lati ẹnu Oluwa.

17. Nwọn wi sibẹ fun awọn ti o ngàn mi pe, Oluwa ti wi pe, Alafia yio wà fun nyin; nwọn si wi fun olukuluku ti o nrìn nipa agidi ọkàn rẹ̀, pe, kò si ibi kan ti yio wá sori nyin.

18. Nitori tali o duro ninu igbimọ Oluwa, ti o woye, ti o si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀? tali o kíyesi ọ̀rọ rẹ̀, ti o si gbà a gbọ́?

19. Sa wò o, afẹfẹ-ìji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori awọn oluṣe buburu:

Jer 23