1. EGBE ni fun awọn oluṣọ-agutan, ti nmu agbo-ẹran mi ṣìna, ti o si ntú wọn ka, li Oluwa wi.
2. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi si oluṣọ-agutan wọnni, ti nṣọ enia mi; Ẹnyin tú agbo-ẹran mi ká, ẹ le wọn junù, ẹnyin kò si bẹ̀ wọn wò, sa wò o, emi o bẹ̀ nyin wò nitori buburu iṣe nyin, li Oluwa wi.
3. Emi o si kó iyokù agbo-ẹran mi jọ lati inu gbogbo ilẹ, ti mo ti le wọn si, emi o si mu wọn pada wá sinu pápá oko wọn, nwọn o bi si i, nwọn o si rẹ̀ si i.
4. Emi o gbe oluṣọ-agutan dide fun wọn, ti yio bọ́ wọn: nwọn kì yio bẹ̀ru mọ́, tabi nwọn kì yio si dãmu, bẹ̃li ọkan ninu wọn kì yio si sọnu, li Oluwa wi.
5. Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.