Ile Dafidi, Bayi li Oluwa wi, Mu idajọ ṣẹ li owurọ, ki o si gba ẹniti a lọ lọwọ gba kuro li ọwọ aninilara, ki ibinu mi ki o má ba jade bi iná, ki o má si jo ti kì o si ẹniti yio pa a, nitori buburu iṣe nyin.