26. Gẹgẹ bi oju ti itì ole nigbati a ba mu u, bẹ̃li oju tì ile Israeli; awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn pẹlu.
27. Ti nwọn wi fun igi pe, Iwọ ni baba mi; ati fun okuta pe, iwọ li o bi mi. Nitori nwọn ti yi ẹ̀hìn wọn pada si mi kì iṣe iwaju wọn: ṣugbọn ni igba ipọnju wọn, nwọn o wipe, Dide, ki o gbani.
28. Njẹ nibo li awọn ọlọrun rẹ wà, ti iwọ ti da fun ara rẹ? jẹ ki nwọn ki o dide, bi nwọn ba le gba ọ nigba ipọnju rẹ, nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃li ọlọrun rẹ, iwọ Juda.
29. Ẽṣe ti ẹnyin o ba mi jà? gbogbo nyin li o ti rufin mi, li Oluwa wi.
30. Lasan ni mo lù ọmọ nyin, nwọn kò gbà ibawi, idà ẹnyin tikara nyin li o pa awọn woli bi kiniun apanirun.
31. Iran enia yi, ẹ kiyesi ọ̀rọ Oluwa. Emi ha ti di aginju si Israeli bi? tabi ilẹ okunkun biribiri, ẽṣe ti enia mi wipe, awa nrin kakiri, awa kì yio tọ̀ ọ wá mọ.