Jer 16:19-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Oluwa, agbara mi ati ilu-odi mi! àbo mi li ọjọ ipọnju! awọn orilẹ-ède yio tọ̀ ọ wá, lati ipẹkun aiye, nwọn o si wipe, Lõtọ, awọn baba wa ti jogun eke, ohun asan, iranlọwọ kò si si ninu wọn!

20. Enia lè ma dá ọlọrun fun ara rẹ̀: nitori awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun?

21. Nitorina, sa wò o, emi o mu ki nwọn ki o mọ̀, lẹ̃kan yi, emi o si mu ki nwọn ki o mọ̀ ọwọ mi ati ipa mi; nwọn o si mọ̀ pe, orukọ mi ni JEHOFA.

Jer 16