7. Emi o fi atẹ fẹ́ wọn si ẹnu-ọ̀na ilẹ na; emi o pa awọn ọmọ wọn, emi o si pa enia mi run, ẹniti kò yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀.
8. Awọn opo rẹ̀ o di pipọ ju iyanrin eti okun: emi o mu arunni wa sori wọn, sori iyá ati ọdọmọkunrin li ọjọkanri; emi o mu ifoya ati ìbẹru nla ṣubu lu wọn li ojiji.
9. Ẹniti o bi meje nṣọ̀fọ o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ; õrùn rẹ̀ wọ̀ l'ọsan, oju ntì i, o si ndamu: iyoku ninu wọn l'emi o si fifun idà niwaju awọn ọta wọn, li Oluwa wi.
10. Egbe ni fun mi, iyá mi, ti o bi mi ni ọkunrin ija ati ijiyan gbogbo aiye! emi kò win li elé, bẹ̃ni enia kò win mi li elé; sibẹ gbogbo wọn nfi mi ré.
11. Oluwa ni, Emi kì o tú ọ silẹ fun rere! emi o mu ki ọta ki o bẹ̀ ọ ni ìgba ibi ati ni ìgba ipọnju!
12. A ha le ṣẹ irin, irin ariwa, ati idẹ bi?
13. Ohun-ini ati iṣura rẹ li emi o fi fun ijẹ, li aigbowo, nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ ni àgbegbe rẹ.