3. Emi si fi iru ijiya mẹrin sori wọn, li Oluwa wi, idà lati pa, ajá lati wọ́ kiri, ẹiyẹ oju-ọrun ati ẹranko ilẹ, lati jẹ, ati lati parun.
4. Emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, nitori Manasse, ọmọ Hesekiah, ọba Juda, nitori eyiti o ti ṣe ni Jerusalemu.
5. Nitori tani yio ṣãnu fun ọ, iwọ Jerusalemu? tabi ti yio sọkun rẹ? tabi tani yio wá lati bere alafia rẹ.
6. Iwọ ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, iwọ ti pada sẹhin; nitorina emi o ná ọwọ mi si ọ, emi o si pa ọ run; ãrẹ̀ mu mi lati ṣe iyọnu.
7. Emi o fi atẹ fẹ́ wọn si ẹnu-ọ̀na ilẹ na; emi o pa awọn ọmọ wọn, emi o si pa enia mi run, ẹniti kò yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀.