17. Emi kò joko ni ajọ awọn ẹlẹgan! ki emi si ni ayọ̀; mo joko emi nikan, nitori ọwọ rẹ: nitori iwọ ti fi ibanujẹ kún mi.
18. Ẽṣe ti irora mi pẹ́ titi, ati ọgbẹ mi jẹ alaiwotan, ti o kọ̀ lati jina? lõtọ iwọ si dabi kanga ẹ̀tan fun mi, bi omi ti kò duro?
19. Nitorina, bayi li Oluwa wi, Bi iwọ ba yipada, nigbana li emi o si tun mu ọ pada wá, iwọ o si duro niwaju mi: bi iwọ ba si yà eyi ti iṣe iyebiye kuro ninu buburu, iwọ o dabi ẹnu mi: nwọn o si yipada si ọ; ṣugbọn iwọ máṣe yipada si wọn.
20. Emi o si ṣe ọ fun awọn enia yi bi odi idẹ ati alagbara: nwọn o si ba ọ jà, ṣugbọn nwọn kì yio le bori rẹ, nitori emi wà pẹlu rẹ, lati gbà ọ là ati lati gbà ọ silẹ, li Oluwa wi.
21. Emi o si gba ọ silẹ kuro lọwọ awọn enia buburu, emi o si rà ọ pada kuro lọwọ awọn ìka.