10. Egbe ni fun mi, iyá mi, ti o bi mi ni ọkunrin ija ati ijiyan gbogbo aiye! emi kò win li elé, bẹ̃ni enia kò win mi li elé; sibẹ gbogbo wọn nfi mi ré.
11. Oluwa ni, Emi kì o tú ọ silẹ fun rere! emi o mu ki ọta ki o bẹ̀ ọ ni ìgba ibi ati ni ìgba ipọnju!
12. A ha le ṣẹ irin, irin ariwa, ati idẹ bi?
13. Ohun-ini ati iṣura rẹ li emi o fi fun ijẹ, li aigbowo, nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ ni àgbegbe rẹ.
14. Emi o si mu ki awọn ọta rẹ kó wọn lọ si ilẹ ti iwọ kò mọ̀: nitoriti iná njo ni ibinu mi, ti yio jo lori rẹ.
15. Oluwa, iwọ mọ̀, ranti mi, bẹ̀ mi wò, ki o si gbẹsan mi lara awọn oninunibini mi! máṣe mu mi kuro nitori ipamọra rẹ: mọ̀ pe, mo ti jiya itiju nitori rẹ!
16. Nigbati a ri ọ̀rọ rẹ, emi si jẹ wọn, ọ̀rọ rẹ si jẹ inu didùn mi, nitori orukọ rẹ li a fi npè mi, iwọ Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun!
17. Emi kò joko ni ajọ awọn ẹlẹgan! ki emi si ni ayọ̀; mo joko emi nikan, nitori ọwọ rẹ: nitori iwọ ti fi ibanujẹ kún mi.
18. Ẽṣe ti irora mi pẹ́ titi, ati ọgbẹ mi jẹ alaiwotan, ti o kọ̀ lati jina? lõtọ iwọ si dabi kanga ẹ̀tan fun mi, bi omi ti kò duro?