11. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Máṣe gbadura fun awọn enia yi fun rere.
12. Nigbati nwọn ba gbãwẹ, emi kì yio gbọ́ ẹ̀bẹ wọn; nigbati nwọn ba ru ẹbọ-ọrẹ sisun ati ẹbọ-ọrẹ, inu mi kì o dùn si wọn: ṣugbọn emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-àrun pa wọn run.
13. Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, sa wò o, awọn woli wi fun wọn pe; Ẹnyin kì yio ri idà, bẹ̃li ìyan kì yio de si nyin; ṣugbọn emi o fun nyin ni alafia otitọ ni ibi yi.