23. Ara Etiopia le yi àwọ rẹ̀ pada, tabi ẹkùn le yi ilà ara rẹ̀ pada? bẹ̃ni ẹnyin pẹlu iba le ṣe rere, ẹnyin ti a kọ́ ni ìwa buburu?
24. Nitorina ni emi o tú wọn ka bi iyangbo ti nkọja lọ niwaju afẹfẹ aginju.
25. Eyi ni ipin rẹ, apakan òṣuwọn rẹ lọwọ mi, li Oluwa wi: nitori iwọ ti gbàgbe mi, ti o si gbẹkẹle eke.
26. Nitorina emi o ka aṣọ iṣẹti rẹ loju rẹ, ki itiju rẹ ki o le hàn sode.
27. Emi ti ri panṣaga rẹ, ati yiyan rẹ bi ẹṣin, buburu ìwa-agbere rẹ, ati ìwa irira rẹ lori oke ati ninu oko. Egbe ni fun ọ, iwọ Jerusalemu! iwọ kò le di mimọ́, yio ha ti pẹ to!