Jer 13:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Emi o tì ekini lu ekeji, ani awọn baba ati awọn ọmọkunrin pọ̀, li Oluwa wi: emi kì yio dariji, bẹ̃ni emi kì o ṣãnu, emi kì yio ṣe iyọ́nu, lati má pa wọn run.

15. Ẹ gbọ́, ki ẹ si fi eti silẹ; ẹ má ṣe gberaga: nitori ti Oluwa ti sọ̀rọ.

16. Ẹ fi ogo fun Oluwa Ọlọrun nyin, ki o to mu òkunkun wá, ati ki o to mu ẹsẹ nyin tase lori oke ṣiṣu wọnni, ati nigbati ẹnyin si nreti imọlẹ, on o sọ ọ di ojiji ikú, o si ṣe e bi òkunkun biribiri.

17. Ṣugbọn bi ẹnyin kì o gbọ́, ọkàn mi yio sọkun ni ibi ikọkọ, nitori igberaga na, oju mi yio sọkun kikan, yio sun omije pẹ̀rẹpẹ̀rẹ, nitori ti a kó agbo Oluwa lọ ni igbekun.

18. Sọ fun ọba ati fun ayaba pe, Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ, ẹ joko silẹ, nitori ade ogo nyin bọ́ si ilẹ lati ori nyin.

19. Ilu gusu wọnni ni a o si mọ, kò si ẹnikan ti yio ṣe wọn: a o kó Judah lọ ni igbekun gbogbo rẹ̀, a o kó wọn lọ patapata ni igbekun.

20. Gbe oju nyin soke, ki ẹ si wo awọn ti mbọ̀ lati ariwa! nibo ni agbo-ẹran nì wà, ti a ti fi fun ọ, agbo-ẹran rẹ daradara?

21. Kini iwọ o wi, nigbati on o fi awọn ti iwọ ti kọ́ lati ṣe korikosun rẹ jẹ olori lori rẹ, irora kì yio ha mu ọ bi obinrin ti nrọbi?

22. Bi iwọ ba si wi ninu ọkàn rẹ pe, Ẽṣe ti nkan wọnyi ṣe wá sori mi? Nitori ti ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ rẹ ni a ṣe ká aṣọ rẹ soke, ti a si fi agbara fi gigisẹ rẹ hàn ni ihoho.

Jer 13