Jer 11:19-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ani mo dabi ọdọ-agutan ti o mọ̀ oju ile, ti a mu wá fun pipa: emi kò si mọ̀ pe, nwọn ti pinnu buburu si mi wipe: Jẹ ki a ke igi na pẹlu eso rẹ̀ ki a si ke e kuro ni ilẹ alãye, ki a máṣe ranti orukọ rẹ̀ mọ.

20. Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun, onidajọ otitọ ti ndan aiya ati inu wò, emi o ri igbẹsan rẹ lori wọn: nitori iwọ ni mo fi ọ̀ran mi le lọwọ.

21. Nitorina bayi li Oluwa wi, niti enia Anatoti ti o nwá ẹmi rẹ, ti nwipe, Máṣe sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa, ki iwọ ki o má ba kú nipa, ọwọ wa.

22. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, wò o, emi o bẹ̀ wọn wo, awọn ọdọmọkunrin o ti ọwọ idà kú, ọmọ wọn ọkunrin ati ọmọ wọn obinrin yio kú nipa iyàn:

23. Ẹnikan kì yio kù ninu wọn: nitori emi o mu ibi wá sori awọn enia Anatoti, ani ọdun ìbẹwo wọn.

Jer 11