2. Nitori bi ọkunrin kan ba wá si ajọ nyin, pẹlu oruka wura, ati aṣọ daradara, ti talakà kan si wá pẹlu li aṣọ ẽri;
3. Ti ẹnyin si bu iyìn fun ẹniti o wọ̀ aṣọ daradara, ti ẹ si wipe, Iwọ joko nihinyi ni ibi daradara; ti ẹ si wi fun talakà na pe, Iwọ duro nibẹ̀, tabi joko nihin labẹ apoti itisẹ mi:
4. Ẹnyin kò ha nda ara nyin si meji ninu ara nyin, ẹ kò ha si di onidajọ ti o ni ero buburu?
5. Ẹ fi etí silẹ, ẹnyin ará mi olufẹ, Ọlọrun kò ha ti yàn awọn talakà aiye yi ṣe ọlọrọ̀ ni igbagbọ́, ati ajogun ijọba na, ti o ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ?
6. Ṣugbọn ẹnyin ti bù talakà kù. Awọn ọlọrọ̀ kò ha npọ́n nyin loju, nwọn kò ha si nwọ́ nyin lọ si ile ẹjọ?
7. Nwọn kò ha nsọ ọrọ-odi si orukọ rere nì ti a fi npè nyin?