17. Nitorina ni Oluwa kì yio ṣe ni ayọ̀ ninu ọdọ-ọmọkunrin wọn, bẹ̃ni ki yio ṣãnu fun awọn alainibaba ati opo wọn: nitori olukuluku wọn jẹ agabagebe ati oluṣe-buburu, olukuluku ẹnu nsọ wère. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
18. Nitori ìwa-buburu njo bi iná: yio jo ẹwọn ati ẹgún run, yio si ràn ninu pàntiri igbó, nwọn o si goke lọ bi ẹ̃fin iti goke.
19. Nipa ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ fi ṣõkùn, awọn enia yio dabi igi iná, ẹnikan kì yio dá arakunrin rẹ̀ si.
20. On o si jajẹ li ọwọ́ ọ̀tun, ebi o si pa a; on o si jẹ li ọwọ́ osì; nwọn kì yio si yo: olukuluku enia yio si jẹ ẹran-ara apa rẹ̀.
21. Manasse o jẹ Efraimu; Efraimu o si jẹ Manasse: awọn mejeji o dojukọ Juda. Ni gbogbo eyi, ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.