12. Awọn ara Siria niwaju, ati awọn Filistini lẹhin: nwọn o si fi gbogbo ẹnu jẹ Israeli run. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
13. Awọn enia na kọ yipada si ẹniti o lù wọn, bẹ̃ni nwọn kò wá Oluwa awọn ọmọ-ogun.
14. Nitorina ni Oluwa yio ke ori ati irù, imọ̀-ọpẹ ati koriko-odo kuro ni Israeli, li ọjọ kan.
15. Agbà ati ọlọla, on li ori, ati wolĩ ti nkọni li eké, on ni irù.
16. Nitori awọn olori enia yi mu wọn ṣìna: awọn ti a si tọ́ li ọ̀na ninu wọn li a parun.