Isa 66:3-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ẹniti o pa akọ-malu, o dabi ẹnipe o pa enia; ẹniti o fi ọdọ-agutan rubọ, a dabi ẹnipe o bẹ́ ajá lọrùn; ẹniti o rubọ ọrẹ, bi ẹnipe o fi ẹ̀jẹ ẹlẹdẹ̀ rubọ; ẹniti o fi turari jona, bi ẹniti o sure fun òriṣa. Nitotọ, nwọn ti yàn ọ̀na ara wọn, inu wọn si dùn si ohun iríra wọn.

4. Emi pẹlu yio yàn itanjẹ wọn, emi o si mu eyi ti nwọn bẹ̀ru wá sara wọn, nitori nigbati mo pè, kò si ẹnikan ti o dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, nwọn kò gbọ́: ṣugbọn nwọn ṣe buburu niwaju mi, nwọn si yàn eyiti inu mi kò dùn si.

5. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ti o nwarìri si ọ̀rọ rẹ̀; Awọn arakunrin nyin ti nwọn korira nyin, ti nwọn ta nyin nù nitori orukọ mi, wipe, Jẹ ki a fi ogo fun Oluwa: ṣugbọn on o fi ara hàn fun ayọ̀ nyin, oju yio si tì awọn na.

6. Ohùn ariwo lati inu ilu wá, ohùn lati inu tempili wá, ohùn Oluwa ti nsan ẹ̀san fun awọn ọta rẹ̀.

7. Ki o to rọbi, o bimọ; ki irora rẹ̀ ki o to de, o bi ọmọkunrin kan.

Isa 66