Isa 66:14-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nigbati ẹnyin ba ri eyi, ọkàn nyin yio yọ̀, egungun nyin yio si tutu yọ̀yọ bi ewebẹ̀; a o si mọ̀ ọwọ́ Oluwa lara awọn iranṣẹ rẹ̀, ati ibinu rẹ̀ si awọn ọta rẹ̀.

15. Nitori kiyesi i, Oluwa mbọ wá ti on ti iná, ati awọn kẹkẹ́ rẹ̀ bi ãjà, lati fi irunu sẹsan ibinu rẹ̀, ati ibawi rẹ̀ nipa ọwọ́ iná.

16. Nitori Oluwa yio fi iná ati idà rẹ̀ ṣe idajọ gbogbo ẹran-ara; awọn okú Oluwa yio si pọ̀.

17. Awọn ti o yà ara wọn si mimọ́, ti nwọn si sọ ara wọn di mimọ́ ninu agbala wọnni, ti ọkan tẹle ekeji li ãrin, nwọn njẹ ẹran ẹlẹdẹ, ati ohun irira, ati eku, awọn li a o parun pọ̀; li Oluwa wi.

Isa 66