1. BAYI ni Oluwa wi, pe, Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si ni apoti itisẹ̀ mi: nibo ni ile ti ẹ kọ́ fun mi gbé wà? ati nibo ni isimi mi gbe wà?
2. Nitori gbogbo nkan wọnni li ọwọ́ mi sa ti ṣe, gbogbo nkan wọnni si ti wà, li Oluwa wi: ṣugbọn eleyi li emi o wò, ani òtoṣi ati oniròbinujẹ ọkàn, ti o si nwarìri si ọ̀rọ mi.
3. Ẹniti o pa akọ-malu, o dabi ẹnipe o pa enia; ẹniti o fi ọdọ-agutan rubọ, a dabi ẹnipe o bẹ́ ajá lọrùn; ẹniti o rubọ ọrẹ, bi ẹnipe o fi ẹ̀jẹ ẹlẹdẹ̀ rubọ; ẹniti o fi turari jona, bi ẹniti o sure fun òriṣa. Nitotọ, nwọn ti yàn ọ̀na ara wọn, inu wọn si dùn si ohun iríra wọn.