4. Awọn ti ngbe inu ibojì, ti nwọn si nwọ̀ ni ile awọn oriṣa, ti njẹ ẹran ẹlẹdẹ, omi-ẹran nkan irira si mbẹ ninu ohun-elò wọn;
5. Ẹniti o wipe, Duro fun ara rẹ, máṣe sunmọ mi; nitori ti mo ṣe mimọ́ jù ọ lọ. Wọnyi li ẹ̃fin ni imu mi, iná ti njo ni gbogbo ọjọ ni.
6. Kiyesi i, a ti kọwe rẹ̀ niwaju mi: emi kì o dakẹ, ṣugbọn emi o gbẹ̀san, ani ẹ̀san si aiya wọn,
7. Aiṣedede nyin, ati aiṣedede awọn baba nyin ṣọkan pọ̀, li Oluwa wi, awọn ẹniti o fi turari jona lori oke-nla, ti nwọn mbu ọla mi kù lori awọn oke kékèké: nitori na li emi o wọ̀n iṣẹ wọn iṣaju, sinu aiya wọn.
8. Bayi ni Oluwa wi, gẹgẹ bi a ti iri ọti-waini titun ninu ìdi eso àjara, ti a si nwipe, Máṣe bà a jẹ nitori ibukun mbẹ ninu rẹ̀: bẹ̃li emi o ṣe nitori awọn iranṣẹ mi, ki emi ki o má ba pa gbogbo wọn run.
9. Emi o si mu iru kan jade ni Jakobu, ati ajogun oke-nla mi lati inu Juda: ayanfẹ mi yio si jogun rẹ̀, awọn iranṣẹ mi yio si gbe ibẹ.
10. Ṣaroni yio di agbo-ẹran, ati afonifoji Akori ibikan fun awọn ọwọ́ ẹran lati dubulẹ ninu rẹ̀, nitori awọn enia mi ti o ti wá mi kiri.
11. Ṣugbọn ẹnyin ti o kọ̀ Oluwa silẹ, ti o gbàgbe oke-nla mimọ́ mi, ti o pèse tabili fun Gadi, ti o si fi ọrẹ mimu kun Meni.
12. Nitorina li emi o ṣe kà nyin fun idà, gbogbo nyin yio wolẹ fun pipa: nitori nigbati mo pè, ẹnyin kò dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, ẹnyin kò gbọ́; ṣugbọn ẹnyin ṣe ibi loju mi, ẹnyin si yàn eyiti inu mi kò dùn si.
13. Nitorina bayi ni Oluwa Jehofah wi, Kiyesi i awọn iranṣẹ mi o jẹun, ṣugbọn ebi yio pa ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o mu, ṣugbọn ongbẹ o gbẹ ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o yọ̀, ṣugbọn oju o tì ẹnyin:
14. Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yio kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹnyin o ke fun ibanujẹ ọkàn, ẹnyin o si hu fun irobinujẹ ọkàn.
15. Ẹnyin o si fi orukọ nyin silẹ fun egún fun awọn ayanfẹ mi: nitori Oluwa Jehofah yio pa ọ, yio si pè awọn iranṣẹ rẹ̀ li orukọ miran:
16. Ki ẹniti o fi ibukun fun ara rẹ̀ li aiye, ki o fi ibukun fun ara rẹ̀ ninu Ọlọrun otitọ; ẹniti o si mbura li aiye ki o fi Ọlọrun otitọ bura; nitori ti a gbagbe wahala iṣaju, ati nitoriti a fi wọn pamọ kuro loju mi.