Isa 65:13-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitorina bayi ni Oluwa Jehofah wi, Kiyesi i awọn iranṣẹ mi o jẹun, ṣugbọn ebi yio pa ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o mu, ṣugbọn ongbẹ o gbẹ ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o yọ̀, ṣugbọn oju o tì ẹnyin:

14. Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yio kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹnyin o ke fun ibanujẹ ọkàn, ẹnyin o si hu fun irobinujẹ ọkàn.

15. Ẹnyin o si fi orukọ nyin silẹ fun egún fun awọn ayanfẹ mi: nitori Oluwa Jehofah yio pa ọ, yio si pè awọn iranṣẹ rẹ̀ li orukọ miran:

16. Ki ẹniti o fi ibukun fun ara rẹ̀ li aiye, ki o fi ibukun fun ara rẹ̀ ninu Ọlọrun otitọ; ẹniti o si mbura li aiye ki o fi Ọlọrun otitọ bura; nitori ti a gbagbe wahala iṣaju, ati nitoriti a fi wọn pamọ kuro loju mi.

17. Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya.

Isa 65