11. Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà?
12. Ti o fi ọwọ́ ọtun Mose dà wọn, pẹlu apá rẹ̀ ti o logo, ti o npin omi meji niwaju wọn, lati ṣe orukọ aiyeraiye fun ara rẹ̀?
13. Ti o mu wọn là ibú ja, bi ẹṣin li aginjù, ki nwọn ki o má ba kọsẹ?
14. Gẹgẹ bi ẹran ti isọ̀kalẹ lọ si afonifoji, bẹ̃ni Ẹmi Oluwa mu u simi: bẹ̃ni iwọ tọ́ awọn enia rẹ, lati ṣe orukọ ti o li ogo fun ara rẹ.
15. Wò ilẹ lati ọrun wá, ki o si kiyesi lati ibugbe ìwa mimọ́ rẹ ati ogo rẹ wá: nibo ni itara rẹ ati agbara rẹ, ọ̀pọlọpọ iyanu rẹ, ati ãnu rẹ sọdọ mi gbe wà? a ha da wọn duro bi?