Isa 61:7-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nipo itijú nyin ẹ o ni iṣẹpo-meji; ati nipo idãmu, nwọn o yọ̀ ninu ipin wọn: nitorina nwọn o ni iṣẹpo-meji ni ilẹ wọn: ayọ̀ ainipẹkun yio jẹ ti wọn.

8. Nitori emi Oluwa fẹ idajọ, mo korira ijale ninu aiṣododo; emi o si fi iṣẹ wọn fun wọn ni otitọ, emi o si ba wọn da majẹmu aiyeraiye.

9. A o si mọ̀ iru wọn ninu awọn Keferi, ati iru-ọmọ wọn lãrin awọn enia, gbogbo ẹniti o ri wọn yio mọ̀ wọn, pé, iru-ọmọ ti Oluwa busi ni nwọn.

Isa 61