Isa 61:10-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Emi o yọ̀ gidigidi ninu Oluwa, ọkàn mi yio yọ̀ ninu Ọlọrun mi; nitori o ti fi agbáda wọ̀ mi, o ti fi aṣọ ododo bò mi, gẹgẹ bi ọkọ iyawó ti iṣe ara rẹ̀ lọṣọ́, ati bi iyawó ti ifi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lọṣọ́.

11. Nitori gẹgẹ bi ilẹ ti imu ẽhù rẹ̀ jade, ati bi ọgbà ti imu ohun ti a gbìn sinu rẹ̀ hù soke; bẹ̃ni Oluwa Jehofah yio mu ododo ati iyìn hù soke niwaju gbogbo orilẹ-ède.

Isa 61