Isa 61:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè.

2. Lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa; lati tù gbogbo awọn ti ngbãwẹ̀ ninu.

Isa 61