4. Kò si ẹniti nwá ẹtọ́, bẹ̃ni kò si ẹniti ndajọ ni otitọ: nwọn gbẹkẹle ohun asan, nwọn nsọ eke; nwọn loyun ikà, nwọn mbí iparun.
5. Nwọn npa ẹyin pamọlẹ, nwọn nhun okùn alantakùn: ẹniti o jẹ ninu ẹyin wọn yio kú, ati eyi ti a tẹ̀ bẹ́ ọká jade.
6. Okùn wọn kì yio di ẹwù, bẹ̃ni nwọn kì yio fi iṣẹ wọn bò ara wọn: iṣẹ wọn ni iṣẹ ikà, iṣe ipá si mbẹ li ọwọ́ wọn.
7. Ẹsẹ wọn sare si ibi, nwọn si yara lati tajẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ: èro wọn èro ibi ni; ibajẹ ati iparun mbẹ ni ipa wọn.
8. Ọ̀na alafia ni nwọn kò mọ̀; kò si idajọ kan ninu ìrin wọn: nwọn ṣe ipa-ọ̀na wiwọ́ fun ara wọn: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ ọ kì yio mọ̀ alafia.
9. Nitori na ni idajọ jìna si wa, bẹ̃ni ododo kì yio le wa bá, awa duro dè imọlẹ, ṣugbọn kiyesi i, okunkun, a duro de imọlẹ, ṣugbọn a nrin ninu okunkun.