Isa 59:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ni rirekọja ati ṣiṣeke si Oluwa, ifaṣẹhin kuro lọdọ Ọlọrun wa, isọrọ inilara ati ìṣọtẹ, liloyun ati sisọrọ eke lati inu jade wá.

14. A dá idajọ pada, ẹtọ́ si duro lokerè rére: otitọ ṣubu ni igboro, aiṣègbe kò le wọ ile.

15. Otitọ kò si, ẹniti o si kuro ninu ibi o sọ ara rẹ̀ di ijẹ: Oluwa si ri i, o si buru loju rẹ̀, ti idajọ kò si.

16. O si ri pe kò si ẹnikan, ẹnu si yà a pe onipẹ̀ kò si, nitorina apá rẹ̀ mu igbala fun u wá; ati ododo rẹ̀, on li o gbé e ró.

17. O si gbe ododo wọ̀ bi awo-aiya, o si fi aṣibori irin igbala dé ara rẹ̀ lori: o wọ̀ ẹwù igbẹsan li aṣọ, a si fi itara wọ̀ ọ bi agbada.

18. Gẹgẹ bi ere iṣe wọn, bẹ̃ gẹgẹ ni yio san a fun wọn, irunú fun awọn ọta rẹ̀, igbẹsan fun awọn ọta rẹ̀; fun awọn erekuṣu yio san ẹsan.

19. Nwọn o si bẹ̀ru orukọ Oluwa lati ìwọ-õrùn wá, ati ogo rẹ̀ lati ilà-õrun wá. Nigbati ọta yio de bi kikún omi, Ẹmi Oluwa yio gbe ọpágun soke si i.

20. Olurapada yio si wá si Sioni, ati sọdọ awọn ti o yipada kuro ninu irekọja ni Jakobu, ni Oluwa wi.

Isa 59