Isa 58:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ.

8. Nigbana ni imọlẹ rẹ yio bẹ́ jade bi owurọ, ilera rẹ yio sọ jade kánkán: ododo rẹ yio si lọ ṣaju rẹ; ogo Oluwa yio kó ọ jọ.

9. Nigbana ni iwọ o pè, Oluwa yio si dahun; iwọ o kigbe, on o si wipe, Emi nĩ. Bi iwọ ba mu àjaga, ninà ika, ati sisọ asan, kuro lãrin rẹ.

10. Bi iwọ ba fà ọkàn rẹ jade fun ẹniti ebi npa, ti o si tẹ́ ọkàn ti a npọ́n loju lọrùn, nigbana ni imọlẹ rẹ yio si là ninu okùnkun, ati okùnkun rẹ bi ọ̀san gangan.

11. Oluwa yio ma tọ́ ọ nigbagbogbo, yio si tẹ́ ọkàn rẹ lọrun ni ibi gbigbẹ, yio si mu egungun rẹ sanra; iwọ o si dabi ọgbà ti a bomirin, ati bi isun omi ti omi rẹ̀ ki itán.

12. Ati awọn tirẹ yio mọ ibi ahoro atijọ wọnni: iwọ o gbé ipilẹ iran ọ̀pọlọpọ ró, a o si ma pe ọ ni, Alatunṣe ẹyà nì, Olumupada ọ̀na wọnni lati gbe inu rẹ̀.

13. Bi iwọ ba yí ẹsẹ rẹ kuro li ọjọ isimi, lati má ṣe afẹ́ rẹ li ọjọ isimi mi; ti iwọ si pè ọjọ isimi ni adùn, ọjọ mimọ́ Oluwa, ọlọ́wọ̀; ti iwọ si bọ̀wọ fun u, ti iwọ kò hù ìwa rẹ, tabi tẹle afẹ rẹ, tabi sọ ọ̀rọ ara rẹ.

14. Nigbana ni inu rẹ yio dùn si Oluwa, emi o si mu ọ gùn ibi giga aiye, emi o si fi ilẹ níni Jakobu baba rẹ bọ́ ọ: nitori ẹnu Oluwa li o ti sọ ọ.

Isa 58