1. OLODODO ṣegbe, kò si ẹniti o kà a si: a mu awọn alãnu kuro, kò si ẹniti nrò pe a mu olododo kuro ṣaju ibi.
2. On wọ̀ inu alafia: nwọn simi lori akete wọn, olukuluku ẹniti nrin ninu iduroṣinṣin rẹ̀.
3. Ṣugbọn ẹ sunmọ ihin, ẹnyin ọmọ oṣo, iru-ọmọ panṣaga on àgbere.
4. Tani ẹnyin fi nṣe ẹsín? tani ẹnyin nyanu gborò si, ti ẹnyin yọ ahọn jade si? ọmọ alarekọja ki ẹnyin, iru-ọmọ eke,