8. Nitori èro mi kì iṣe èro nyin, bẹ̃ni ọ̀na nyin kì iṣe ọ̀na mi, li Oluwa wi.
9. Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bẹ̃ni ọ̀na mi ga ju ọ̀na nyin lọ, ati èro mi ju èro nyin lọ.
10. Nitori gẹgẹ bi òjo ati ojo-didì ti iti ọrun wá ilẹ, ti kì isi tun pada sọhun, ṣugbọn ti o nrin ilẹ, ti o si nmu nkan hù jade ki o si rudi, ki o le fi irú fun awọn afúnrúgbìn, ati onjẹ fun ọjẹun: