Isa 54:3-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nitori iwọ o ya si apa ọtún ati si apa osì, iru-ọmọ rẹ yio si jogun awọn keferi: nwọn o si mu ki awọn ilu ahoro wọnni di ibi gbigbe.

4. Má bẹ̀ru, nitori oju kì yio tì ọ: bẹ̃ni ki o máṣe dãmu; nitori a ki yio doju tì ọ; nitori iwọ o gbagbe itìju igbà ewe rẹ, iwọ kì yio sì ranti ẹ̀gan iwà-opo rẹ mọ.

5. Nitori Ẹlẹda rẹ li ọkọ rẹ; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀; ati Olurapada rẹ Ẹni-Mimọ Israeli; Ọlọrun agbaiye li a o ma pè e.

6. Nitori Oluwa ti pè ọ bi obinrin ti a kọ̀ silẹ, ti a si bà ni inu jẹ, ati bi aya igba ewe nigbati a ti kọ̀ ọ, li Ọlọrun rẹ wi.

7. Ni iṣẹju diẹ ni mo ti kọ̀ ọ silẹ, ṣugbọn li ãnu nla li emi o kó ọ jọ:

8. Ni ṣiṣàn ibinu li emi pa oju mi mọ kuro lara rẹ ni iṣẹju kan! ṣugbọn õre ainipẹkun li emi o fi ṣãnu fun ọ; li Oluwa Olurapada rẹ wí.

Isa 54