3. Nitori bayi li Oluwa wi, a ti tà nyin lọfẹ, a o si rà nyin pada laisanwo.
4. Nitori bayi li Oluwa Jehofa wi, Awọn enia mi sọkalẹ lọ si Egipti li atijọ lati ṣe atipo nibẹ; ara Assiria si ni wọn lara lainidi.
5. Njẹ nisisiyi, Oluwa wipe, Kini mo nṣe nihin, ti a kó awọn enia mi lọ lọfẹ? awọn ti o jọba wọn mu nwọn kigbe, li Oluwa wi; titi lojojumọ li a si nsọ̀rọ odì si orukọ mi.
6. Nitorina awọn enia mi yio mọ̀ orukọ mi li ọjọ na: nitori emi li ẹniti nsọrọ: kiyesi i, emi ni.