1. NISISIYI, emi o kọ orin si olufẹ ọwọ́n mi, orin olùfẹ mi ọwọ́n niti ọ̀gba àjara rẹ̀. Olufẹ ọwọ́n mi ni ọ̀gba àjara lori okè ẹlẹtù loju:
2. O si sọ ọ̀gba yi i ka, o si ṣà okuta kuro ninu rẹ̀, o si gbìn ayànfẹ àjara si inu rẹ̀, o si kọ ile iṣọ sãrin rẹ̀, o si ṣe ifunti sinu rẹ̀ pẹlu: o si wò pe ki o so eso, ṣugbọn eso kikan li o so.
3. Njẹ nisisiyi, ẹnyin ara Jerusalemu ati ẹnyin ọkunrin Juda, emi bẹ̀ nyin, ṣe idajọ lãrin mi, ati lãrin ọ̀gba àjara mi.
4. Kini a ba ṣe si ọ̀gba àjara mi ti emi kò ti ṣe ninu rẹ̀, nigbati mo wò pe iba so eso, ẽṣe ti o fi so eso kikan?
5. Njẹ nisisiyi, ẹ wá na, emi o sọ ohun ti emi o ṣe si ọ̀gba àjara mi fun nyin: emi o mu ọ̀gba rẹ̀ kuro, a o si jẹ ẹ run, emi o wo ogiri rẹ̀ lu ilẹ, a o si tẹ̀ ẹ mọlẹ.
6. Emi o si sọ ọ di ahoro, a kì yio tọ́ ẹka rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio wà a, ṣugbọn ẹ̀wọn ati ẹ̀gún ni yio ma hù nibẹ, emi o si paṣẹ fun awọsanma ki o má rọjò sori rẹ̀.
7. Nitori ọ̀gba àjara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ile Israeli, ati awọn ọkunrin Juda ni igi-gbìgbin ti o wù u, o reti idajọ, ṣugbọn kiyesi i, inilara; o si reti ododo; ṣugbọn kiyesi i, igbe.
8. Egbe ni fun awọn ti o ni ile kún ile, ti nfi oko kún oko, titi ãyè kò fi si mọ, ki nwọn bà le nikan wà li ãrin ilẹ aiye!
9. Li eti mi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ pe, Nitõtọ ọ̀pọ ile ni yio di ahoro, ile nla ati daradara laisi olugbe.