Isa 49:24-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. A ha le gba ikogun lọwọ alagbara bi? tabi a le gbà awọn ondè lọwọ awọn ẹniti nwọn tọ́ fun?

25. Ṣugbọn bayi ni Oluwa wi, a o tilẹ̀ gbà awọn ondè kuro lọwọ awọn alagbara, a o si gbà ikogun lọwọ awọn ẹni-ẹ̀ru; nitori ẹniti o mba ọ jà li emi o ba jà, emi o si gbà awọn ọmọ rẹ là.

26. Awọn ti o ni ọ lara li emi o fi ẹran ara wọn bọ́, nwọn o mu ẹjẹ ara wọn li amuyo bi ọti-waini didùn: gbogbo ẹran-ara yio si mọ̀ pe, Emi Oluwa ni Olugbala ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara ti Jakobu.

Isa 49