Isa 49:12-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Kiye si i, awọn wọnyi yio wá lati ọ̀na jijìn: si wò o, awọn wọnyi lati ariwa wá; ati lati iwọ-õrun wá, ati awọn wọnyi lati ilẹ Sinimu wá.

13. Kọrin, ẹnyin ọrun; ki o si yọ̀, iwọ aiye; bú jade ninu orin, ẹnyin oke-nla: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, yio si ṣãnu fun awọn olupọnju rẹ̀.

14. Ṣugbọn Sioni wipe, Oluwa ti kọ̀ mi silẹ; Oluwa mi si ti gbagbe mi.

15. Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ.

16. Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo.

17. Awọn ọmọ rẹ yára; awọn oluparun rẹ ati awọn ti o fi ọ ṣofò yio ti ọdọ rẹ jade.

18. Gbe oju rẹ soke yika kiri, si kiyesi i: gbogbo awọn wọnyi ṣà ara wọn jọ, nwọn si wá sọdọ rẹ. Oluwa wipe, Bi mo ti wà, iwọ o fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bi ohun ọṣọ́, nitõtọ, iwọ o si há wọn mọ ara, bi iyawo.

Isa 49