Isa 46:8-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ẹ ranti eyi, ẹ si fi ara nyin hàn bi ọkunrin: ẹ gbà a si ọkàn, ẹnyin alarekọja.

9. Ẹ ranti nkan iṣaju atijọ: nitori emi li Ọlọrun, ko si si ẹlomiran, emi li Ọlọrun, ko si si ẹniti o dabi emi.

10. Ẹniti nsọ opin lati ipilẹṣẹ wá, ati nkan ti kò ti iṣe lati igbãni wá, wipe, Imọ mi yio duro, emi o si ṣe gbogbo ifẹ mi.

Isa 46