5. Tani ẹnyin o fi mi we, ti yio si ba mi dọgba, ti ẹ o si fi mi jọ, ki awa le jẹ ọ̀gba?
6. Nwọn da wura lati inu apò wá, nwọn si fi iwọ̀n wọ̀n fadaka, nwọn bẹ̀ alagbẹdẹ wura, o si fi i ṣe oriṣa: nwọn tẹriba, nwọn si nsìn.
7. Nwọn gbe e le ejika, nwọn rù u, nwọn si fi i sipò rẹ̀; o si duro: ki yio kuro ni ipò rẹ̀; nitõtọ, ẹnikan yio kọ si i, ṣugbọn ki yio dahùn: bẹ̃ni ki yio gbà a kuro ninu wahala rẹ̀.
8. Ẹ ranti eyi, ẹ si fi ara nyin hàn bi ọkunrin: ẹ gbà a si ọkàn, ẹnyin alarekọja.