Isa 46:3-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Gbọ́ ti emi, iwọ ile Jakobu, ati gbogbo iyoku ile Israeli, ti mo ti gbe lati inu wá, ti mo ti rù lati inu iyá wá.

4. Ani titi de ogbó emi na ni; ani titi de ewú li emi o rù nyin; emi ti ṣe e, emi o si gbe, nitõtọ emi o rù, emi o si gbàla.

5. Tani ẹnyin o fi mi we, ti yio si ba mi dọgba, ti ẹ o si fi mi jọ, ki awa le jẹ ọ̀gba?

6. Nwọn da wura lati inu apò wá, nwọn si fi iwọ̀n wọ̀n fadaka, nwọn bẹ̀ alagbẹdẹ wura, o si fi i ṣe oriṣa: nwọn tẹriba, nwọn si nsìn.

Isa 46