1. BELI tẹriba, Nebo bẹrẹ̀, oriṣa wọn wà lẹhin awọn ẹranko, ati lẹhin ohun-ọ̀sin; a di ẹrù wiwo rù nyin; ẹrù fun awọn ẹranko ti ãrẹ̀ mu.
2. Nwọn bẹ̀rẹ, nwọn jumọ tẹriba; nwọn kò le gbà ẹrù na silẹ, ṣugbọn awọn tikala wọn lọ si igbèkun.
3. Gbọ́ ti emi, iwọ ile Jakobu, ati gbogbo iyoku ile Israeli, ti mo ti gbe lati inu wá, ti mo ti rù lati inu iyá wá.