Isa 44:9-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Asan ni gbogbo awọn ti ngbẹ ere; nkan iyebiye wọn ki yio si lerè; awọn tikala wọn li ẹlẹri ara wọn: nwọn kò riran, bẹ̃ni nwọn kò mọ̀; ki oju ba le tì wọn.

10. Tani yio gbẹ́ oriṣa, tabi ti yio dà ere ti kò ni ère kan?

11. Kiyesi i, oju o tì gbogbo awọn ẹgbẹ́ rẹ̀; awọn oniṣọna, enia ni nwọn: jẹ ki gbogbo wọn kò ara wọn jọ, ki nwọn dide duro; nwọn o bẹ̀ru, oju o si jumọ tì wọn.

12. Alagbẹdẹ rọ ãke kan, o ṣiṣẹ ninu ẹyín, o fi ọmọ-owú rọ ọ, o si fi agbara apá rẹ̀ ṣe e: ebi npa a pẹlu, agbara rẹ̀ si tan; ko mu omi, o si rẹ̀ ẹ.

13. Gbẹnàgbẹnà ta okùn rẹ̀, o si fi nkan pupa sàmi rẹ̀, o fi ìfá fá a, o si fi kọmpassi là a birikiti: o sì yá a li aworán ọkunrin, gẹgẹ bi ẹwà enia, ki o le ma gbe inu ile.

14. O bẹ́ igi kedari lu ilẹ fun ra rẹ̀, o si mu igi kipressi ati oaku, o si mu u le fun ra rẹ̀ ninu awọn igi igbó: o gbìn igi aṣi, ojò si mu u dagba.

15. Nigbana ni yio jẹ ohun idana fun enia: nitori yio mu ninu wọn, yio si fi yá iná; lõtọ, o dá iná, o si din akara, lõtọ, o ṣe ọlọrun fun ra rẹ̀, o si nsìn i; o gbẹ ẹ li ere, o si nforibalẹ fun u.

16. Apakan ninu rẹ̀ li o fi dá iná, apakan ninu rẹ̀ li o fi jẹ ẹran: o sun sisun, o si yo, o yá iná pẹlu, o si wipe, Ahã, ara mi gbona, mo ti ri iná.

17. Iyokù rẹ̀ li o si fi ṣe ọlọrun, ani ere gbigbẹ́ rẹ̀, o foribalẹ fun u, o sìn i, o gbadura si i, o si wipe, Gbà mi; nitori iwọ li ọlọrun mi.

18. Nwọn kò mọ̀, oye ko si ye wọn: nitori o dí wọn li oju, ki nwọn ki o má le ri; ati aiya wọn, ki oye ki o má le ye wọn.

19. Kò si ẹniti o rò li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ni ko si imọ̀ tabi oye lati wipe, Mo ti fi apakan rẹ̀ da iná; mo si din akara pẹlu lori ẹyin iná rẹ̀: mo ti sun ẹran, mo si jẹ ẹ: emi o ha fi iyokù rẹ̀ ṣe irira? emi o ha foribalẹ fun ìti igi?

20. O fi ẽru bọ́ ara rẹ̀: aiya ẹtàn ti dari rẹ̀ si apakan, ti kò le gbà ọkàn rẹ̀ là, bẹ̃ni kò le wipe, Eke ko ha wà li ọwọ́ ọtun mi?

21. Ranti wọnyi, Jakobu ati Israeli; nitori iwọ ni iranṣẹ mi: Emi ti mọ ọ; iranṣẹ mi ni iwọ, Israeli; iwọ ki yio di ẹni-igbagbe lọdọ mi.

22. Mo ti pa irekọja rẹ rẹ́, bi awọsanma ṣiṣú dùdu, ati ẹ̀ṣẹ rẹ, bi kũku: yipada sọdọ mi; nitori mo ti rà ọ pada.

23. Kọrin, ẹnyin ọrun; nitori Oluwa ti ṣe e: kigbe, ẹnyin isalẹ aiye; bú si orin, ẹnyin oke-nla, igbó, ati gbogbo igi inu rẹ̀; nitori Oluwa ti rà Jakobu pada, o si ṣe ara rẹ̀ logo ni Israeli.

24. Bayi ni Oluwa, Olurapada rẹ wi, ati ẹniti o mọ ọ lati inu wá: emi li Oluwa ti o ṣe ohun gbogbo; ti o nikan nà awọn ọrun; ti mo si tikara mi tẹ́ aiye.

25. Ẹniti o sọ àmi awọn eke di asan, ti o si bà awọn alafọṣẹ li ori jẹ, ti o dá awọn ọlọgbọn pada, ti o si sọ imọ̀ wọn di wère.

26. Ti o fi ìdi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ̀ mulẹ, ti o si mu ìmọ awọn ikọ̀ rẹ̀ ṣẹ; ti o wi fun Jerusalemu pe, A o tẹ̀ ọ dó; ati fun gbogbo ilu Juda pe, A o kọ́ nyin, emi o si gbe gbogbo ahoro rẹ̀ dide:

Isa 44