11. Emi, ani emi ni Oluwa; ati lẹhin mi, kò si olugbala kan.
12. Emi ti sọ, mo ti gbalà, mo si ti fi hàn, nigbati ko si ajeji ọlọrun kan lãrin nyin: ẹnyin ni iṣe ẹlẹri mi, li Oluwa wi, pe, Emi li Ọlọrun.
13. Lõtọ, ki ọjọ ki o to wà, Emi na ni, ko si si ẹniti o le gbani kuro li ọwọ́ mi: emi o ṣiṣẹ, tani o le yi i pada?
14. Bayi li Oluwa, olurapada nyin, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Nitori nyin ni mo ṣe ranṣẹ si Babiloni, ti mo si jù gbogbo wọn bi isansa, ati awọn ara Kaldea, sisalẹ si awọn ọkọ̀ igbe-ayọ̀ wọn.
15. Emi ni Oluwa, Ẹni-Mimọ́ nyin, ẹlẹda Israeli Ọba nyin.
16. Bayi li Oluwa wi, ẹniti o la ọ̀na ninu okun, ati ipa-ọ̀na ninu alagbara omi;
17. Ẹniti o mu kẹkẹ ati ẹṣin jade, ogun ati agbara; nwọn o jumọ dubulẹ, nwọn kì yio dide: nwọn run, a pa wọn bi owú fitila.
18. Ẹ máṣe ranti nkan ti iṣaju mọ, ati nkan ti atijọ, ẹ máṣe rò wọn.
19. Kiyesi i, emi o ṣe ohun titun kan; nisisiyi ni yio hù jade; ẹnyin ki yio mọ̀ ọ bi? lõtọ, emi o là ọ̀na kan ninu aginju, ati odò li aṣalẹ̀.
20. Awọn ẹran igbẹ yio yìn mi logo, awọn dragoni ati awọn owiwi; nitori emi o funni li omi li aginjù, ati odo ni aṣalẹ̀, lati fi ohun mimu fun awọn enia mi, ayanfẹ mi;
21. Awọn enia yi ni mo ti mọ fun ara mi; nwọn o fi iyìn mi hàn.
22. Ṣugbọn iwọ kò ké pe mi, Jakobu; ṣugbọn ãrẹ̀ mu ọ nitori mi, iwọ Israeli.
23. Iwọ ko mu ọmọ-ẹran ẹbọ sisun rẹ fun mi wá; bẹ̃ni iwọ ko fi ẹbọ rẹ bu ọlá fun mi. Emi ko fi ọrẹ mu ọ sìn, emi ko si fi turari da ọ li agara.
24. Iwọ ko fi owo rà kalamu olõrun didun fun mi, bẹ̃ni iwọ ko fi ọra ẹbọ rẹ yó mi; ṣugbọn iwọ fi ẹ̀ṣẹ rẹ mu mi ṣe lãla, iwọ si fi aiṣedẽde rẹ da mi li agara.
25. Emi, ani emi li ẹniti o pa irekọja rẹ rẹ́ nitori ti emi tikalami, emi ki yio si ranti ẹ̀ṣẹ rẹ.
26. Rán mi leti: ki a jumọ sọ ọ; iwọ rò, ki a le da ọ lare.
27. Baba rẹ iṣãju ti ṣẹ̀, awọn olukọni rẹ ti yapa kuro lọdọ mi.
28. Nitorina mo ti sọ awọn olori ibi mimọ́ na di aimọ́, mo si ti fi Jakobu fun egún, ati Israeli fun ẹ̀gan.