Isa 42:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WÒ iranṣẹ mi, ẹniti mo gbéro: ayànfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si; mo ti fi ẹmi mi fun u: on o mu idajọ wá fun awọn keferi.

2. On kì yio kigbé, bẹ̃ni kì yio gbé ohùn soke, bẹ̃ni kì yio jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro.

3. Iyè fifọ́ ni on ki yio ṣẹ, owú ti nrú ẹ̃fin ni on kì yio pa: yio mu idajọ wá si otitọ.

4. Ãrẹ̀ kì yio mú u, a kì yio si daiyà fò o, titi yio fi gbé idajọ kalẹ li aiye, awọn erekùṣu yio duro de ofin rẹ̀.

5. Bayi ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹniti o dá ọrun, ti o si nà wọn jade; ẹniti o tẹ̀ aiye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹniti o fi ẽmi fun awọn enia lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti o nrin ninu rẹ̀:

6. Emi Oluwa li o ti pè ọ ninu ododo, emi o si di ọwọ́ rẹ mu, emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, imọlẹ awọn keferi.

7. Lati là oju awọn afọju, lati mu awọn ondè kuro ninu tubu, ati awọn ti o joko li okùnkun kuro ni ile tubu.

8. Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹ̃ni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́.

9. Kiyesi i, nkan iṣãju ṣẹ, nkan titun ni emi si nsọ: ki nwọn to hù, mo mu nyin gbọ́ wọn.

Isa 42