Isa 40:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ tù enia mi ninu, ẹ tù wọn ninu, ni Ọlọrun nyin wi.

2. Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo.

Isa 40