5. Lori olukuluku ibùgbe oke Sioni, ati lori awọn apejọ rẹ̀, li Oluwa yio si da awọsanma, ati ẹ̃fin li ọsan, ati didan ọwọ́ iná li oru: nitori àbò yio wá lori gbogbo ogo.
6. Agọ kan yio si wà fun ojiji li ọsan kuro ninu oru, ati fun ibi isasi, ati fun ãbo kuro ninu ijì, ati kuro ninu ojò.