ATI li ọjọ na obinrin meje yio dimọ́ ọkunrin kan, wipe, Awa o jẹ onjẹ ara wa, awa o si wọ̀ aṣọ ara wa: kìkì pe, jẹ ki a fi orukọ rẹ pè wa, lati mu ẹgàn wa kuro.